OSUWON TI CALGARY FUN IREWESI OKAN NINU AISAN


OPOLO TIO NFA IDARU LARIN IBASEPO


ERO OKAN ATI IHUWASI


Aforo wa ni lenu wo: Bere ibere akoko bi a se ko. Lo awon ibere te tele bi o ti ro wipe o ye si. Akoko ti awon ibere won yi nye wo je lati ose meji sehin lai je wipe ayi pada.

Akiyesi: Ibere kesan da le ori awon akiyesi re nigba ifi oro wa ni lenu wo naa.

1. Irewesi okan: Ba wo ni o se ma se apejuwe okan re si lati bi ose meji sehin? Se o ni oyaya bi ti atehin wa tabi irewesi okan ba o? Lati ose meji sehin, bi igba melo ni (lo awon oro ti eni naa so) ma mba o lojumo? Se gbogbo igba lojojumo ni?

0

Kosi  
1 Die Ogba pe ibanuje die tabi aini iyanju wa.
2 Niwonba Odaju wipe irewesi okan wa fun idaji igba lati ose meji sehin: owa lojojumo.
3 Pupo Irewesi okan pupo wa fun opo igba lojojumo ti o si ndi ise ati ajogbepo re lowo.

2. Ai ni ireti: Bawo ni ose ri ojo ola re si? Se oro wipe ojo ola re yio dara tabi o ti so ireti nu? Se o ti su o tabi idi wa ti o fi ni lati ma gbiyanju?

0 Kosi  
1 Die Nigbamiran larin ose meji sehin oti so ireti nu sugbon, o si ni ireti die fun ojo ola.
2 Niwonba O so ireti nu niwonba ni opo igba larin ose meji sehin. Okan re se yi pada lati gba wipe ojo ola si le dara.
3 Pupo Ainireti ni gbogbo igba ti o si nfa inilara pupo fun.

3. Fifi oju kekere wo ara eni: Bawo ni o se ri ara re si tio ba fi ara re we awon elomiran? Se o dara ju, o dara to tabi o kan dara bi awon elomiran ni? Se oro wipe okere si won tabi oko tile jamo nkankan?

0 Kosi  
1 Die Olero wipe oun kere sugbon ko ro wipe oun ko jamo nkankan.
2 Niwonba Olero wipe oun ko jamo nkankan sugbon fun akoko ti ko to ida meji ose meji sehin.
3 Pupo Olero wipe oun ko jamo nkankan fun opolopo igba. O le gba wipe kori be e.

4. Riro wipe a nda oun lebi: Se o lero wipe awon eniyan nda o lebi fun nkankan tabi won nfi esun kan o lai to? Nipa kini? (Mase ka awon esun ati ida lebi tio ye kun)

0 Kosi  
1 Die Fun igba die, oro wipe a nda oun lebi, sugbon won ko wipe a nfi esun kan han.
2 Niwonba Ero lera lera wipe won nda oun lebi, ati/tabi ero lekokan wipe a nfi esun kan oun.
3 Pupo Ero lera lera wipe a nfi esun kan oun. O gba wipe kori be tio ba bawi.

5. Dida ara eni lebi laito: Se oma nda ara re lebi fun awon nkan kekeke tio ti sehin? Se olero wipe oye ki awon nkan wonyi ma dun o lokan?

0 Kosi  
1 Die O ma nda ara re lebi ju lori awon asise ti ko to nkan, sugbon fun igba die sehin ni.
2 Niwonba O nda ara re lebi (ni igba pupo) lori awon nkan ti oti se sehin, osi nbu kun awon nkan naa.
3 Pupo O ro wipe oun ni oye ki a da lebi fun gbogbo nkan ti o ti baje, bo ti leje wipe kii se oun lo fa awon nkan naa.

6. Irewesi okan ni araro: Ni awon igba ti o ti ni irewesi okan lati bii ose meji sehin se o ti se akiyesi wipe irewesi naa ma npo ju ni awon akoko kan? 

0 Kosi  
1 Die Irewesi okan wa sugbon ko po ni awon akoko kan ju omiran lo.
2 Niwonba Irewesi okan ti o so fun ara re wipe o npoju ni araro.
3 Pupo Irewesi okan ti o po pupo ni aro, ti osi ndi ise re lowo sugbon ti o nro ni owo irole.

7. Jiji sile ni aro kutu: Nje o ma nji sile ni aro kutu ni akoko ti o ro wipe ko ye fun o? Igba melo lose ni eyi ma nsele?

0 Kosi  
1 Die Lekokan, o ma ntete ji (to bi emeji lose) si le bi wakati kan tabi ju be lo si igba ti o ye fun.
2 Niwonba Nigba pupo o ma ntete ji (to bi ijo marun lose) si le bi wakati kan tabi ju be lo si igba ti o ye fun.
3 Pupo Lojojumo o ma ntete ji bi wakati kan tabi ju be lo si igba ti o ye fun.

8. Pipa ara eni: Nje o ti dabi eni wipe aye su o? Se o ti ro wipe ki o pa ara re? Kini o ro wipe o ma se? Se o ti gbiyanju ati pa ara re?

0 Kosi  
1 Die Lore kore o ti ro wipe osan ti oun ba ti ku, tabi lekokan o ti ro wipe ki o pa ara re.
2 Niwonba O ti moomo gbero ati pa ara re, sugbon ko ti gbiyanju ati se be.
3 Pupo O ti gbiyanju nipa ona ti o han gbangba wipe o fe pa ara re ni (iyen ni wipe: aba ni aye nitoripe ona ti ogba lati pa ara re kii se ona ti o to lati pa a).

9. Irewesi okan ti o se akiyesi re: Da le ori awon nkan tio se akiyesi re nigba ifi oro wani lenu wo naa. Ibere yi ‘Se o dabi eni wipe kio sokun?’ tio lo ni awon igba ti o ye nigba ifi oro wa ni lenu wo naa, o le fa awon nkan tio wulo lati dahun ibere yi jade.

0 Kosi  
1 Die O ba oju je bi eni ti inu re ko dun, ti ofo se papa nigba ti o bere awon nkan ti ko mu oro edun okan lowo.
2 Niwonba O ba oju je bi eni ti inu re ko dun, ti ofo se nigbogbo akoko ifi oro wa ni lenu wo naa, ohun re si lo sile bi eni fe sokun.
3 Pupo O sokun nigba ti o nsoro nipa awon iponju re, lore kore o nmi kanle o si bu sekun, tabi o dabi eni wipe o gan ti kosi mira rara nitori irora okan ti o ba da o loju wipe nkan tio nsele niyen.

 

Translated by:
Dr. Babatunde Olarinde
Senior Registrar
Psychiatric Hospital
#8, Harvey Road, Yaba
PMB 2008, Lagos
Nigeria
Tel: +234-1-7743174, ext. 248
 
Send e-mail